Monday, July 13, 2009

ERO AMUNA WA PA EEYAN META LEKOO.

Ariwo ekun ni o so ni agbegbe Ibiye, ni Morogbo, agbegbe Agbadarigi ni Ipinle Eko, ni opin ose nigba ti iroyin iku oko ati iyawo kan ati iya iyawo te won lowo latari eefin ero amuna wa naa ti o pa won.
Awon omo won meji wa ni ile iwosan ti a ko mo, sugbon won ti gbe oku awon oku meteeta lo si aaye igboku si ile iwosan apapo ti Badagiri.
Ekunrere alaye oun ti o pa won si sokunkun, sugbon awon olopaa ni oku awon eeyan naa pelu awon omo won obinrin meji ti won da ku ni awon olopaa pelu iranlowo awon ara adugbo gbe jade ni ano lati inu ile won.
Awon olopaa ni won wa bi igba ti eeyan sun ni nigba ti awon wole lati lo ran won lowo ninu iyara kan soso ti won n gbe nigba ti awon de be.
Alukoro awon olopaa ni Ipinle Eko , Ogbeni Frank Mba salaye pe awon olopaa n wa di isele naa lowo.

GOMINA DANIEL ATI AWON OSERE RANTI OGUNDE LEYIN ODUN 19

Gomina Ipinle Ogun, Gbenga Daniel pelu awon egbe osere darapo mo awon ebi, ni opin ose, ti o koja lati se iranti oloogbe Hubert Ogunde, eni ti o ku ni odun 19 seyin.
Ni ibi ayeye naa ti won ti si ere oloogbe naa, Gomina Daniel sapejuwe oloogbe naa gege bi eni itan, ti oruko re ko pare bi odun se n gori odun, ti osu n gori osu.
Daniel se ileri pe ijoba ohun yoo ni ifowosowopo pelu awon ebi Ogunde lati da abule fiimu ti o ba ti agbaye mu sile loruko Ogunde ni Ososa, ilu oloogbe naa.

Friday, July 3, 2009

AYANGALU DAGBERE FAYE NI OMO ODUN 65.

Onilu pataki kan ti gbogbo eeyan mo si Ayangalu, iyen Ayantunji Amoo ti ta teru nipa o.
Gege bi atejade ti Ogbeni Tunde Kilani, onse fiimu pataki te jade fun awon oniroyin, Ayangalu ku ni Ojobo ano, won si sin ni ojo kan naa gege bi ilana musulumi.
Kelani ni a gbo iro iku ayan naa pelu ibanuje ni owuro yii. Iku re tun ti din okan ku ninu awon agbaoje idi ilu ti o tun ku ni ile yooba.
Won ni o ba won se ninu ere Oba Koso, Awon Omemu, Saworoide ati Agogoeewo ati awon ere miran lorisirisi.

GBENGA DANIEL GBENA WOJU AGBENUSO ILE IGBIMO ASOFIN AGBA.

Wahala kan ti o jo ere idaraya sele ni ojobo ano, ni agbegbe Sango, ni Ipinle Ogun, nigba ti gomina Gbega Daniel koju oludamoran Agbenuso Ile Igbimo Asofin Agba lori igbohun soke sodo, Oloye Kayode Odunaro ni gbangba.
Awon ti o te le gomina ati awon ero iworan ri bi Daniel se koju oludamoran naa pe ki lo n se ni ori afara ti won n se lowo.
Gomina ti o se abewo lo si ijoba Ibile AdoOdo/Ota duro nigba ti o ri awon eeyan ti won n dari awon osise ile ise ero amohunmaworan ti won ya ise ti won n se pelu Odunaro lori afara naa.
Daniel ti awon osise ijoba tele leyin wa duro, o bi Odunaro pe ki ni eyin eeyan yii n se nibi, a bi eyin ni e tun moju to ise yii ni.
Oludamoran naa ko tete soro, o kan rerin pe "olola julo, a kan n wo ise ti won n se ni, won ti bere lati ojoAje".
Daniel wa kuro niwaju re nigba ti o fesi re tan.
Ipinle naa ati Agbenuso Agba Saburi Dimeji Bankole ti n se bi ologbo ati ekute lati igba ti agbenuso naa ti kede pe ijoba apapo ti san owo bilionu 1.5 bi ose meloo kan seyin pe ki won fi pari ise naa.

ADAJO PASE KI OGA OLOPAA MA MU AGBEJORO AREGBESOLA.

Ile Ejo giga kan ni Ipinle Eko ti pase pe ki oga agba olopaa ma se fi owo ofin mu Agba Agbejoro ile Naijiria, Ogbeni Kola Awodein.
Ile ejo naa tun pase fun awon olopaa pe ki won si da atimu agba agbejoro naa duro, titi ti ile ejo yoo fi yiri oro ti o wa nile naa wo.
Awodein je okan ninu awon agba agbejoro ti o n gbejo ro fun oludije fun ipo gomina Ipinle Osun, labe asia egbe onigbale(Action Congress), Ogbeni Rauf Aregbesola, ohun ni o be ile ejo lati gba ohun lowo awon olopaa nipa dida abo bo eto ijomoeniyan ohun.
Won ni awon olopaa ti n gbero ati mu Awodein ti mole, fun pe o safihan akosile awon olopaa lati gbeja Aregbesola, eyi ti awon olopaa ni ayederu ni.
Sugbon agba agbejoro naa ni ki agbejoro ohun Ogbeni Babatunde Fagbohunlu (Agba Agbejoro), fi iwe esun sile lodo Adajo Afeez Dabiri labe iwe ofin ile waodun 1999.
O pe oga agba olopaa ati ijoba Ipinle Osun gege bi olujejo si esun re. Fagbohunlu ro ile ejo lati gba ipe eni ti o ran ohun nise wole.
Nigba ti o gbo oro enu Fagbohunlu tan, Adajo Dabiri pase pe ki oga olopaa ati awon osise re dekun lati mu, tiimole, fiyaje tabi hale mo atimu Awodein.
O ni gbigba laaye ti ohun gba olufisun naa laaye kari gbogbo esun ti o wa nile, titi ti ohun yoo fi yiri oro ejo ti o wa nile wo tan.
Ile ejo naa tun gba Awodein laye lati fun awon olujejo ni Abuja ati Osun ni abajade esun naa.
Won ti sun igbejo di ojo 14, osu agemo ti a wa yii.