Friday, August 7, 2009

BOKO HARAM: ENI ESU NI WON O -- SULTAN

Sultan ile Sokoto ti so pe awon olori esin musulumi ti setan lati koju ati lati segun iwa esu ti o n lo lowo ni Bauchi, Borno, Kano ati Ipinle Yobe.
Abubakar, ninu oro ti o so pelu ikapa re gege bi Aare Jama'atul Nasril Islam ati Nigerian Supreme Council of Islamic Affairs, so pe ni iwon igba ti esin Islam ko faaye gba darudapo, oun ko ni fi aaye gba egbe apaayan kan tabi egbe alagbapa.
O ni awon musulumi ati esin Islam ko lowo si idoju ko awon agbofinro, ati fifi eje alaise sofo ti o n lo lowo ni awon ipinle mererin ti Boko Haram ti n da ilu ru.
Sultan naa tun ni ona buburu kan re lati ba oruko rere orile ede yii je niwaju ajo agbaye ti a ko si ni gba.
O wa ro gbogbo Musulumi lati ran ijoba lowo pelu awon agbofinro lowo lati kese jari nibi sise iwadi lori oro idaluru Boko Haram ati awon olori re.

WA OJUTU SI ORO AABO, ONOVO.

Ajo awon gomina ile Naijiria ki oga olopaa tuntun Ogbeni Ogbonaya Onovo ku oriire ti ipo tuntun pelu imoran pe ki o ba wa dekun iwa janduku ati ai ni ibale okan.
Ki Aare Yar'adua to so di oga olopaa tuntun ni Ojoru ti o koja, o ti n soju fun Ogbeni Mike Okiro ti o jowo aaaye re ni ojo24, osu keje odun yii.
Awon gomina ro pe won ti royin re gege bi akoni ti o mo ise re se, ti o si ma n yege ninu gbogbo ise ti won ba fun se, won wa ni ki o tete bere ise ki o si se atunse si ise olopaa ati ki o si se eto aabo ti o peye fun awon ara ilu, awon paa paa ko ni sin lati ran an lowo nibi ti o ba to ati ibi ti o ye lati le kese jari ise re.

OWO MEKA GBOWO LORI

Ajo ti o n moju to irinajo meka iyen NAHCON, salye ni ano pe idi ti owo meka odun yii yoo fi gbowo leri ni pasiparo owo naira si dola.
Komisonati o n gbenuso fun NAHCON, Dokita Saleh Okenwa so fun awon oniroyin lanaa pe ida 12% ti o gori owo naa ko sai da lori pasiparo owo naira si dola, pelu awon idi miran.
O ni awon ti o n lo si ile Meka san owo N470,736 si N588,709, o da lori ibi ti onikaluku ti fe gbe ra ati iru awon ti o m ba lo. O ni pasiparo dola ti o je $1 si N117 lodun to koja ti di $1 si N147 ni odun yii.

AWON AJINIGBE JI ALAGA KANSU MEJI GBE O

Alaga Ijoba Ibile Igalamela/Odolu, Hon. Ernest Abah ati Alaga Iwoorun Yagba(West), Hon. Ropo Asala ni a gbo pe won ji gbe ni ano ni ile itura kan ni Kabba.
Awon mejeeji lo si igboro lati lo kopa nibi ipade awon alaga ijoba ibile ti won ma n se ni osoosu ni ipinle naa ni.
Awon ajinigbe naa pa meta ninu awon olopaa ti o n tele won, nigba ti awon olopaa pa eyo kan ninu awon ajinigbe naa.
Awon ajinigbe naa ti de si ile itura naa ni nkan bii aago meje owuro ninu oko Toyota Hilux ti awon olopaa meji ti won si ko nnkan ija oloro dani tepon.
Asoju alaga ibile Okene, Hon. Yahaya Karaku ti won m pe ni Yakubu ati direba re ti won sese gan an ni won ti ko lo si ile iwosan nla kan ni Lokoja fun iwosan.
A tun gbo pe awon ajinigbe naa tun kede pe ki awon alaga to ku bo sita laijebe, eyi ti won ba ka mo inu ile yoo da ara re lebi, eyi ni o mu ki gbogbo won bere sii ni jade ti won fi ni ki won ma dobale sile ki won ma doju bole.
A gbo pe ni asale ano, awon ajinigbe naa pe komisona fun eto ijoba ibile ati oro loyeloye, Ogbeni Toluwaju Faniyi pelu foonu Abbah pe awon yoo gba milionu 60 owo naira lati fi won sile.

ETO ISUNA 2010, GBOGBO YIN LE O DASI.

Ile Igbimo Asofin Agba, iyen sineti ti so pe eto isuna odun 2010, gbogbo ara ilu lo laaanfani ati dasi.
Alaga Ajo Sineti lori oro isuna, iyen Sineto Iyiola Omisore ni o so eyi di mimo pe gbogbo eeyan ti oro ba kan ni yoo lanfani ati dasi oro eto isuna odun 2010 nitori awon yoo te pepe re sile fun gbogbo awon ti oro ba kan ni lati so ero ti won.
O so eyi di mimo nigba ti o n soro nibi apeje kan ni ilu Abuja ni ana lori oro bi eto isuna owo yoo se ma je nnkan ti o han si awon ara ilu, o ni lati le mu ki eyi je sise, awon yoo kan si awon ti oro ba kan kaakiri origun mefefa orile ede yii.

Monday, July 13, 2009

ERO AMUNA WA PA EEYAN META LEKOO.

Ariwo ekun ni o so ni agbegbe Ibiye, ni Morogbo, agbegbe Agbadarigi ni Ipinle Eko, ni opin ose nigba ti iroyin iku oko ati iyawo kan ati iya iyawo te won lowo latari eefin ero amuna wa naa ti o pa won.
Awon omo won meji wa ni ile iwosan ti a ko mo, sugbon won ti gbe oku awon oku meteeta lo si aaye igboku si ile iwosan apapo ti Badagiri.
Ekunrere alaye oun ti o pa won si sokunkun, sugbon awon olopaa ni oku awon eeyan naa pelu awon omo won obinrin meji ti won da ku ni awon olopaa pelu iranlowo awon ara adugbo gbe jade ni ano lati inu ile won.
Awon olopaa ni won wa bi igba ti eeyan sun ni nigba ti awon wole lati lo ran won lowo ninu iyara kan soso ti won n gbe nigba ti awon de be.
Alukoro awon olopaa ni Ipinle Eko , Ogbeni Frank Mba salaye pe awon olopaa n wa di isele naa lowo.

GOMINA DANIEL ATI AWON OSERE RANTI OGUNDE LEYIN ODUN 19

Gomina Ipinle Ogun, Gbenga Daniel pelu awon egbe osere darapo mo awon ebi, ni opin ose, ti o koja lati se iranti oloogbe Hubert Ogunde, eni ti o ku ni odun 19 seyin.
Ni ibi ayeye naa ti won ti si ere oloogbe naa, Gomina Daniel sapejuwe oloogbe naa gege bi eni itan, ti oruko re ko pare bi odun se n gori odun, ti osu n gori osu.
Daniel se ileri pe ijoba ohun yoo ni ifowosowopo pelu awon ebi Ogunde lati da abule fiimu ti o ba ti agbaye mu sile loruko Ogunde ni Ososa, ilu oloogbe naa.