Friday, August 7, 2009

BOKO HARAM: ENI ESU NI WON O -- SULTAN

Sultan ile Sokoto ti so pe awon olori esin musulumi ti setan lati koju ati lati segun iwa esu ti o n lo lowo ni Bauchi, Borno, Kano ati Ipinle Yobe.
Abubakar, ninu oro ti o so pelu ikapa re gege bi Aare Jama'atul Nasril Islam ati Nigerian Supreme Council of Islamic Affairs, so pe ni iwon igba ti esin Islam ko faaye gba darudapo, oun ko ni fi aaye gba egbe apaayan kan tabi egbe alagbapa.
O ni awon musulumi ati esin Islam ko lowo si idoju ko awon agbofinro, ati fifi eje alaise sofo ti o n lo lowo ni awon ipinle mererin ti Boko Haram ti n da ilu ru.
Sultan naa tun ni ona buburu kan re lati ba oruko rere orile ede yii je niwaju ajo agbaye ti a ko si ni gba.
O wa ro gbogbo Musulumi lati ran ijoba lowo pelu awon agbofinro lowo lati kese jari nibi sise iwadi lori oro idaluru Boko Haram ati awon olori re.

1 comment:

  1. Alagba o daju wipe alaimokan mokan nipa EsinIslam ni eniti o ko itan yi. Gege bi omo Yoruba, o jo mi loju wipe o si tun wa lara awa omo Kaaro-o-jiire ti nwon fe di eru fun awon omo Biafra ti o n gbogun ti isokan orile ede Naijiriya.

    O ti le ni ogoji odun sehin ti awon omo Biafra ti bere ete ati da oju orile ede Naijiriya bole. Awon alaimokan mokan lati ipase esin ajose ti Kiriyo pelu awon omo Biafra ko ni ironu nipa ete yi.

    Ki ni o le to bee ti omo Yoruba ko i ronu. Awon Boko Haram bere ija nwon laari ose kan pere ko sisi eniti o so nipa idarijin nwon ki awon oga olopa ti opolopo nwon je ara Biafra to bere sipa kukuru sipa gungun ni ilu Hausa.

    Ni osu ti awa yi irohin gbode nipa eto idarinji (Amnesty) ti awon yibo fun Yar'Adua lorun lati se fun awon olosa (criminals), ole ati adaluru ni Niger Delta. Awon olosa nwonyi ti beere si ni pa ogunlogo awon eniyan lara awon omo Naijiriya ati awon ti kiise Naijiriya. Kilode kilose ti awon Kiriyo Yoruba ko ko itan nipa eleyi nibi.

    Ope ni fun olohun wipe awa omo Yoruba ti a n ko eko labe Sheikh Dr. (Abu-Abdullah Adelabu) Baba-Abdullah Adelabu ni ile okere ti riran ju bi osi, aimokan, tembelekun ati eleya meya ti ba Yoruba je lo.

    Enikeni ti o ba wa nidi itan yi ni lati ko eko nipa EsinIslam esin alaafia lee di ara wa ni Awqaf Africa ti o wa ni Ilu London ati America nipase www.esinislam.com ati www.islamafrica.com ati www.awqafafrica.com

    Nibayi ko si awawi fun omo Yoruba mo wipe nwon ko ni anfaani lati ka nipa EsinIslam. Oniruru onimimo iwe ati Kewu ti wa laarin awa omo Yoruba. Abi taani ko gbo nipa akitiyan awon akeko Sheikh Adelabu ni London? Ti a ba ri iru eni bee, ki o se abewo si www.esinislam.com ti awon omo Africa da sile ni Oyinbo Geesi.

    Taani eni esu gan an naa? Se awon olosa Niger Delta ni o wa je omo orile-ede rere ti nwon fi to si Eto-Aforinjin yi. Egbeegberun owo ni Naijiriya ti sofo latori ija-n-duku awon omo Biafra yii. Epo ti sofo lo, emi ti sofo lo, ohun ini ti sofo lo ninu ija buruku ti awon omo biafra gbe koju isokan orile-ede wa. Kinide ti awon Kiriyo Naijiriya fi dojule awon eniyan wa ni oke oya to be ti nwon gbagbe akitiyan ti own jagunjagun Yoruba bi Jehunbewon ati Baba Iyabo ja lati di isokan orile ede Naijiriya mu?

    Mo fi asiko yi kesi awon akotan Yoruba yi ki nwon o se iwadi ti o to ati iwadi ti oye nipa Boko Haram ati ohun ti o fa ti iru isele ti nwon bee fi waye. Opolopo awon omo Yoruba, Hausa ati Ibo ti ko pupo lori eyi fun awon esinisla.com. A leri ka nibe fun eko, oye, ati imo laiko fi igbakan bo ikan ninu.


    Oluko Itan yi ni:

    Hafiz Adesokan
    Okan ninu Awon-akeko Sheikh Dr. Adelabu
    Ni Awqaf Africa - London

    ReplyDelete