Wednesday, June 3, 2009

ILE IGBIMO ASOFIN PASE PE KI ALAGA KANSU DA OWO OSU PADA.

Ile Igbimo Asofin Ipinle Ogun ti ro alaga fidi e Erekusu Ijebu (Ijebu-North), Omoba Wale Osiyemi lanaa pe ki o da owo ti o na, owo osu ti o gba ati gbogbo eto ti o je gege bi alaga fidi e pada lati igba ti o ti gba ijoba lowo alaga ti won dibo yan.
Ile Igbimo naa ti tu isejoba fidie naa ka lati ose ti o koja, lori esun pe Gomina Gbenga Daniel kan se ni arumoje ni lona ti ko bofin mu.
Alaga ti won di ibo yan ni agbegbe naa, Ogbeni Tele Ogunjobi, ni Daniel jawe jokoo le fun ni nnkan bi osu marun seyin, latari pe ohun ni o wa leyin wahala ti o sele ni Olu Ile Egbe PDP ni Abeokuta lodun to koja, ti o si mu emi eeyan meta lo.
Osu marun leyin igba ti o ti yo, Daniel ko ti da pada, eyi ti o mu ki Ile Igbimo Asofin so pe iwa ti Daniel wu yi ko bojumu, ko si ba ofin mu.
Abati ano waye ni gbagede Ile Igbimo naa latenu Asofin Adijat Adeleye-Oladapo ti o n soju Ifo 2, nigba ti Asofin Abiodun Micheal Akovoyo ti o n soju Ipokia, se gbe lese.

No comments:

Post a Comment