Showing posts with label IROYIN. Show all posts
Showing posts with label IROYIN. Show all posts

Friday, August 7, 2009

BOKO HARAM: ENI ESU NI WON O -- SULTAN

Sultan ile Sokoto ti so pe awon olori esin musulumi ti setan lati koju ati lati segun iwa esu ti o n lo lowo ni Bauchi, Borno, Kano ati Ipinle Yobe.
Abubakar, ninu oro ti o so pelu ikapa re gege bi Aare Jama'atul Nasril Islam ati Nigerian Supreme Council of Islamic Affairs, so pe ni iwon igba ti esin Islam ko faaye gba darudapo, oun ko ni fi aaye gba egbe apaayan kan tabi egbe alagbapa.
O ni awon musulumi ati esin Islam ko lowo si idoju ko awon agbofinro, ati fifi eje alaise sofo ti o n lo lowo ni awon ipinle mererin ti Boko Haram ti n da ilu ru.
Sultan naa tun ni ona buburu kan re lati ba oruko rere orile ede yii je niwaju ajo agbaye ti a ko si ni gba.
O wa ro gbogbo Musulumi lati ran ijoba lowo pelu awon agbofinro lowo lati kese jari nibi sise iwadi lori oro idaluru Boko Haram ati awon olori re.

OWO MEKA GBOWO LORI

Ajo ti o n moju to irinajo meka iyen NAHCON, salye ni ano pe idi ti owo meka odun yii yoo fi gbowo leri ni pasiparo owo naira si dola.
Komisonati o n gbenuso fun NAHCON, Dokita Saleh Okenwa so fun awon oniroyin lanaa pe ida 12% ti o gori owo naa ko sai da lori pasiparo owo naira si dola, pelu awon idi miran.
O ni awon ti o n lo si ile Meka san owo N470,736 si N588,709, o da lori ibi ti onikaluku ti fe gbe ra ati iru awon ti o m ba lo. O ni pasiparo dola ti o je $1 si N117 lodun to koja ti di $1 si N147 ni odun yii.

AWON AJINIGBE JI ALAGA KANSU MEJI GBE O

Alaga Ijoba Ibile Igalamela/Odolu, Hon. Ernest Abah ati Alaga Iwoorun Yagba(West), Hon. Ropo Asala ni a gbo pe won ji gbe ni ano ni ile itura kan ni Kabba.
Awon mejeeji lo si igboro lati lo kopa nibi ipade awon alaga ijoba ibile ti won ma n se ni osoosu ni ipinle naa ni.
Awon ajinigbe naa pa meta ninu awon olopaa ti o n tele won, nigba ti awon olopaa pa eyo kan ninu awon ajinigbe naa.
Awon ajinigbe naa ti de si ile itura naa ni nkan bii aago meje owuro ninu oko Toyota Hilux ti awon olopaa meji ti won si ko nnkan ija oloro dani tepon.
Asoju alaga ibile Okene, Hon. Yahaya Karaku ti won m pe ni Yakubu ati direba re ti won sese gan an ni won ti ko lo si ile iwosan nla kan ni Lokoja fun iwosan.
A tun gbo pe awon ajinigbe naa tun kede pe ki awon alaga to ku bo sita laijebe, eyi ti won ba ka mo inu ile yoo da ara re lebi, eyi ni o mu ki gbogbo won bere sii ni jade ti won fi ni ki won ma dobale sile ki won ma doju bole.
A gbo pe ni asale ano, awon ajinigbe naa pe komisona fun eto ijoba ibile ati oro loyeloye, Ogbeni Toluwaju Faniyi pelu foonu Abbah pe awon yoo gba milionu 60 owo naira lati fi won sile.

ETO ISUNA 2010, GBOGBO YIN LE O DASI.

Ile Igbimo Asofin Agba, iyen sineti ti so pe eto isuna odun 2010, gbogbo ara ilu lo laaanfani ati dasi.
Alaga Ajo Sineti lori oro isuna, iyen Sineto Iyiola Omisore ni o so eyi di mimo pe gbogbo eeyan ti oro ba kan ni yoo lanfani ati dasi oro eto isuna odun 2010 nitori awon yoo te pepe re sile fun gbogbo awon ti oro ba kan ni lati so ero ti won.
O so eyi di mimo nigba ti o n soro nibi apeje kan ni ilu Abuja ni ana lori oro bi eto isuna owo yoo se ma je nnkan ti o han si awon ara ilu, o ni lati le mu ki eyi je sise, awon yoo kan si awon ti oro ba kan kaakiri origun mefefa orile ede yii.

Friday, July 3, 2009

GBENGA DANIEL GBENA WOJU AGBENUSO ILE IGBIMO ASOFIN AGBA.

Wahala kan ti o jo ere idaraya sele ni ojobo ano, ni agbegbe Sango, ni Ipinle Ogun, nigba ti gomina Gbega Daniel koju oludamoran Agbenuso Ile Igbimo Asofin Agba lori igbohun soke sodo, Oloye Kayode Odunaro ni gbangba.
Awon ti o te le gomina ati awon ero iworan ri bi Daniel se koju oludamoran naa pe ki lo n se ni ori afara ti won n se lowo.
Gomina ti o se abewo lo si ijoba Ibile AdoOdo/Ota duro nigba ti o ri awon eeyan ti won n dari awon osise ile ise ero amohunmaworan ti won ya ise ti won n se pelu Odunaro lori afara naa.
Daniel ti awon osise ijoba tele leyin wa duro, o bi Odunaro pe ki ni eyin eeyan yii n se nibi, a bi eyin ni e tun moju to ise yii ni.
Oludamoran naa ko tete soro, o kan rerin pe "olola julo, a kan n wo ise ti won n se ni, won ti bere lati ojoAje".
Daniel wa kuro niwaju re nigba ti o fesi re tan.
Ipinle naa ati Agbenuso Agba Saburi Dimeji Bankole ti n se bi ologbo ati ekute lati igba ti agbenuso naa ti kede pe ijoba apapo ti san owo bilionu 1.5 bi ose meloo kan seyin pe ki won fi pari ise naa.

ADAJO PASE KI OGA OLOPAA MA MU AGBEJORO AREGBESOLA.

Ile Ejo giga kan ni Ipinle Eko ti pase pe ki oga agba olopaa ma se fi owo ofin mu Agba Agbejoro ile Naijiria, Ogbeni Kola Awodein.
Ile ejo naa tun pase fun awon olopaa pe ki won si da atimu agba agbejoro naa duro, titi ti ile ejo yoo fi yiri oro ti o wa nile naa wo.
Awodein je okan ninu awon agba agbejoro ti o n gbejo ro fun oludije fun ipo gomina Ipinle Osun, labe asia egbe onigbale(Action Congress), Ogbeni Rauf Aregbesola, ohun ni o be ile ejo lati gba ohun lowo awon olopaa nipa dida abo bo eto ijomoeniyan ohun.
Won ni awon olopaa ti n gbero ati mu Awodein ti mole, fun pe o safihan akosile awon olopaa lati gbeja Aregbesola, eyi ti awon olopaa ni ayederu ni.
Sugbon agba agbejoro naa ni ki agbejoro ohun Ogbeni Babatunde Fagbohunlu (Agba Agbejoro), fi iwe esun sile lodo Adajo Afeez Dabiri labe iwe ofin ile waodun 1999.
O pe oga agba olopaa ati ijoba Ipinle Osun gege bi olujejo si esun re. Fagbohunlu ro ile ejo lati gba ipe eni ti o ran ohun nise wole.
Nigba ti o gbo oro enu Fagbohunlu tan, Adajo Dabiri pase pe ki oga olopaa ati awon osise re dekun lati mu, tiimole, fiyaje tabi hale mo atimu Awodein.
O ni gbigba laaye ti ohun gba olufisun naa laaye kari gbogbo esun ti o wa nile, titi ti ohun yoo fi yiri oro ejo ti o wa nile wo tan.
Ile ejo naa tun gba Awodein laye lati fun awon olujejo ni Abuja ati Osun ni abajade esun naa.
Won ti sun igbejo di ojo 14, osu agemo ti a wa yii.

Tuesday, June 30, 2009

OKIRO PASE KI AWON INILE ITURA MA MORUKO AWON ALEJO WON WA LOJOOJUMO

Oga Agba olopaa yanyan, Ogbeni Mike Okiro, ti pase fun awon onile itura ni orile ede yii, pe ki won ma mu idanimo awon ayale gbe won wa si odo awon olopaa ni ojojumo.
O ni eyi se pataki nitori yoo je ki awon olopaa le mo onka iye awon eeyan ti o n wole ati jade kuro ni orile ede yii lojoojumo.
Okiro tun ni ti a ko ba moju to awon eto igbafe wa, won le lo ona igbafe lati fi ko ba aabo orile ede wa.
Oga Agba Olopaa naa so eyi di mimo, nigba ti o n gba alejo Oga Agba Eto Igbafe, (NTDC), Ogbeni Segun Runsewe, ni ofiisi re.
O tun ni, lati isinyii lo, awon olusowo ile itura ati aye igbafe miran gbodo ma wo igbese awon ti won ba lalejo, ki won si ma ta olopaa lolobo, ti won ba kofiri ajeji igbese kan.

MO N FI IGBO SE OOGUN NI -- OLUJEJO

Oro kan se bi awada lanaa ni Ile Ejo Giga Ijoba Apapo ni Eko nigba ti olujejo omo odun 48 kan, Wahab Ahmed, so fun ile ejo pe ohun ko ta igbo, sugbon ohun fi n se egbogi arunmoleegun ati awon egbogi miran ni.
Ajo ti o n gbogun ti egbogi oloro ni ile wa, iyen NDLEA, mu olujejo naa lo si ile ejo pelu esun eyo kan pe o n ta igbo niwaju Adajo Binta Murtala-Nyako pe won ka mo pelu igbo ti o won kilo 1.5 lai ni ase ati se bee.
Won ni o se ese naa ni ojo 24, osu keta odun yii, ni agbegbe Dada Bello, ni Ayilate, Agege, Ilu Eko.
Gege bi ajo NDLEA ti wi, ese re naa lodi si ofin abala 11(c) ti ajo NDLEA, Ori N30, ofin Ile wa Naijiria, 2004.
Eni ti won fi esun kan naa ti o ni ohun pari iwe mewa ni odun 1981, gba pe ohun jebi esun naa.
O so siwaju si i pe ohun ma n mu igbo, sugbon ohun ko ti ta igbo ri laye ohun. O ni"o ma n fun mi lokun ati agbara lati le se ise daradara.
"Mo tun ma n fi eyi to gbo sile re se oogun arunmoleegun, ati ogun ti ko ni je ki awon omode mu igbo mo."
Agbejoro ajo NDLEA wa ro adajo lati dajo fun Ahmed bi o ti to ati bi o ti ye.
Adajo Murtala-Nyako da ejo fun Ahmed pe ki o lo si ewon osu merin, ki ounka re bere lati ojo ti won ti mu.

Monday, June 29, 2009

AWON OLOPAA N PA EEYAN SERE NI

Ni igbakeji laipe si ara won, ofin ti ijoba Eko se pe ki won ma mo iku to pa eeyan ki won to sin tun ti se afihan bi awon olopaa se n si ibon won lo pa eeyan sere.
Ayewo ti won se si iku to pa oloogbe Modebayo Awosika labe ofin Coroner naa ti odun 2007, so pe awon olopaa lo se iku pa arakunrin naa lona aito.
Ile Ejo Majisireti ti o wa ni Tapa ni Eko ti Magisireti Agba Phillip Ojo se adari re so pe ni igba ti awon ye esi korona naa wo, o han gbangba pe ibon awon olopaa lo se iku ojiji pa oloogbe naa.

AGBATAN NI KI E GBA WA O, OGAGUN IJAW

Ogbeni Solomon Ngbara, okan ninu awon olori ajagunta Ijaw ti o wa lati apa Ogoni ni Ipinle Rivers ti ke gbajare si ijoba apapo pe agbatan ni ki o gba awon ti o ba ti se tan lati jowo ara won.
Eyi n wa ye lasiko ti Aare Yar'adua n gboriyin fun awon ajagunta naa ti won ti se tan fun ati ko ibon sile di omo tuntun pe ki alaafia le joba ni agbegbe naa ati orile ede Naijiria lapapo.

Tuesday, June 16, 2009

AWON OLOPAA MU IGBAKEJI AGBENUSO IPINLE EKITI.

Leyin bii osu meji ti awon olopaa ti kede pe awon n wa igbakeji Agbenuso Ile Igbimo Asofin, owo awon olopaa Ipinle Ekiti ti ba Ogbeni Saliu Adeoti ni ano, ti won si fi si ahamo, lori esun pe o lowo si jijo olu ile ise ajo eleto idibo, ni agbegbe Ido-Osi ni lori oro atundi eto ijoba ipinle naa ti o koja.
Won ni won mu ni ile re ti o wa ni agbegbe Otun-Ekiti ni nnkan bi aago kan ano.

AWON AJAGUN IJAW GBA LATI KI OWO OMO WON BO ASO.

Olori awon Ajagun ijaw, iyen Tom Ateke ti o koju awon ologun lowolowo, ti gba pe awon yoo ji owo omo awon bo aso, sugbon o m beere fun iru aforiji ti ijoba apapo yoo fun awon jagunjagun awon, ki awon le mo bi awon se ma se eto ipalemo ati ko ohun ija sile kia kia.
Gbigba lati gba aabo aforiji ijoba ti Ateke gba waye leyin ti awon egbe ajagun miran tun n leri pe awon yoo di ere boolu ife agbaye to m bo lowo.
Agbejoro fun awon jagun jagun ijaw naa, Ogbeni Ikenna Enekweizu, so pe eni ti o gbese fun ohun naa, ti o ti koju orisirisi ija pelu awon ologun ijoba ti se tan lati joo ija nigba ti o pe apejo awon oniroyin ilu Pota ni ano.
Agbejoro naa ni eni ti o be ohun ni se, ti se tan lati pada si Okirika lati lo darapo mo ilosiwaju to n lo ni be.

Monday, June 15, 2009

INA JO OPA EPO ROBI.

Isele ijamba ina tun sele nilu Eko ni ojo Abameta 13, ti o koja ni Ilado, ni itosi aaye itoju epo si Atlas Cove ti ile ise epo robi NNPC.
Eyi sele leyin iru re kan ti o sele ninu osu Igbe (April), ti o koja, ni agbegbe Mosimi ni Ipinle Ogun.
Agbenuso ile ise opa epo PPMC Ogbeni Ralph Ugwu, so pe isele buburu naa n wa waye latari awon ti o nji epo robi wa ni.
O ni awon egbe naa n sise pelu oko mokanla, ti won fi n ji epo wa. Bi won se ri awon eso ogun oju omi ti o m bo ti won fe salo ni isele naa sele.
Awon oniroyin wa hu gbo pe ina jo awon oko won sugbon won ri ona abayo lati sa asala fun emi won.

AWON GOMINA JAWE GBELE E.

A ti hu gbo pe o da bi eni pe ajo awon gomina ile wa Naijiria ti jawe gbele e awon o lo si ile ile unifasiti Havard, ni Boston, Ile America mo.
E ni ti o salaye oro naa so wi pe ariwo ti awon eeyan pa le awon gomina naa ni o fa ti won fi jo o lilo si ile iwe ti won fe lo fun igbeko naa.
Eyi ni o tele pipada bo awon merin kan ti won ti koko lo se iwadi lori oro Havard ati awon ile eko miran ni ilu ohun ni nnkan bii ose meji seyin.
Iwe Iroyin ile Naijiria kan ti ko pe asoju ile eko naa ti so pe ko si akosile ko kan laaarin oun ati awon gomina ile Naijiria pe awon m bo fun igbeko nilu awon.
Eyi ni a gbo pe o doju tii won julo ti won fi wa jawe gbele e fun ra a won.
A gbo pe gbogbo awon gomina ile Naijiria ni won pete pero pe ki gbogbo awon Gomina 36 lo kuro ni ilu yii fun igbeko ni Ilu oyinbo, eyi ti o ti fe fi ori sopon bayii.

Sunday, June 14, 2009

AWON OMO NAIJIRIA SE AYEYE JUNE 12.

Ogun logo awon omo Naijiria lo se ayeye isami odun 16, ayajo ojo June 12, 1993, ti a se idibo Ijoba Apapo ti won ni o kese jari julo ni ile Naijiria, ti won so pe Oloye Mosudi Olawale Kasimawo Abiola jawe olubori julo, sugbon ti ko raye de ipo naa.
Orisirisi imoran ni o jeyo fun ijoba lori ona ati se iranti ojo naa ni ile wa Naijiria, ti oloogbe gbe naa ti o ku si ahamo ijoba ni ojo7,osu 7 odun 1998, latari pe o n beeere fun eto re .
Gomina meji ni ile wa Naijiria, iyen Eko ati Ogun ni won ya ojo naa soto fun awon osise won lati sami ayajo ojo naa.
Gomina Babatunde Raji Fashola so wi pe oku ibo naa yoo si ma le awon omo Naijiria ki ri ayafi ti ijoba ba le se eto lati san ojo fun esi idibo naa ti o yarati julo ni orile ede wa Naijiria.

EGBE OKUNKUN WA NIDI EPO ROBI.

Adari ajo to n moju to oro epo robi (NNPC), tele ri, iyen Dokita Jackson Gaius-Obaseki, ni ojo Bo ti o koja ti so fun Ajo Alabe Sekele Ile Igbimo Asofin Agba ti o n yiri aise deede idi ajo naa wo pe ohun ba ajo naa rudurudu, ni odun 1999, awon ile ise epo kan wa ti won ni iwe ase ati ma a gbon epo robi di odun 2016.
Ko tako tabi gba wole pe ajo naa ni ogbon alumo koroyi ti o n se pelu awon ile ise elepo, sugbon Obaseki so wi pe idi ni yi ti ohun fi doju ija ko awon egbe imule idi epo naa ni odun 1999 ti ohun gba ijoba.
O ni ohun ni lati gba awon iwe ase naa nigba ti ohun ri pe awon ajo elepo naa ko gba ona ti o mo lati ma se ise won.

E FI EJE TORO OSOTIMEHIN RO AWON OMO NAIJIRIA

Lati dekun ri ra eje ti o ti labawon lowo awon ti o n ta eje orisirisi kiri nitori owo, Minisita fun eto Ilera, Kofeso Babatunde Osotimehin ti ro awon omo Naijiria lati ma a fi eje toro ni ofe fun anfa ni atile ni anito fun eto ilera to peye.
Minisita ti o pe ipeyi nilu Abuja lasiko ti o n ba awon oniroyin soro, nibi ayeye ayajo Ojo Awon Afeje Toro L'agbaye, so pe ona kan lati le je ki anito, aabo, ati pipo ba oro eje, ni lati ri eje gba lodo awon ti o n fi eje toro la i gba owo lori re.

Friday, June 5, 2009

AJO ONIROYIN EKO SO LADI LAWAL LORUKO.

Ajo awon oniroyin ile Naijiria, eka ti Eko (NUJ), ni ola ode yii, yoo yi oruko olu ile egbe won ati sekiteria won pada si oruko alaga won ti o ku, Alhaji Ladi Lawal.
Yiyi oruko olu ile egbe naa pada si Ladi Lawal Press Centre je okan lara ona ti egbe naa fe fi ranti Aaare egbe naa, gomina Adams Oshiomhole ti ipinle Edo ni yoo si dari re.
Ayeye ranpe naa ti o ma waye ni bii aago 9 owuro si aago11 ni ojule 9a Adugbo Iyalla, Alausa, Ikeja ni be awon eeyan yoo raye lati gboriyin fun akoni naa ti o lo.
Ladi Lawal, omo odun 54, ti o ku ni Abuja bi ose meji seyin, se Alaga fun egbe naa l'Ekoo ni eemeji ati Aare egbe naa fun Naijiria ni odun 1994 si 1995.

KADUNA FI ENI YE LUKA SI.

Ijoba ipinle Kaduna ti ya eni so to gege bi ojo ko si ise fun awon ara ilu lati ye oloogbe ogagun Agba Luka Yusuf, ti o ku ni ojo 2, osu yii.
Atejade ti asoju ijoba fun (eto iroyin eto gbagba), iyen Umar Sani fowo si salaye pe pelu isinmi eni, gbogbo ise ijoba ni o ti yi pada, paapa julo eto abewo kaaakiri gbogbo ijoba ibile ti o n se lowo ni awon yoo tu sun si ojo iwaju.
"Gomina ki gbogbo awon ebi oloogbe naa, Ile ise ologun ile wa, pelu gbogbo omo ipinle yii pe a ku araferaku omo wa ti o lo, yoo si ro wa loju fun ogidi omo ti o sise takuntakun sin ilu re".

ELEWO TUNTUN YOO GBA OPA ASE LOLA.

Elewo ti ilewo tuntun ni Abeokuta, ipinle Ogun, Oba Akindele Orisabiyi, Elewo dodo bi oke 11, yoo gba opa ase lola.
Oba Elewo ti o ti wa ni ipebi lati igba ti gomina ti gba yiyan re wole, ni Gomina Gbenga Daniel yoo gbe opa ase fun lola gege bi Oba.
Oba ti won bi ni bi odun 67 seyin je akeko jade Yunifasiti Obafemi Awolowo, Ile Ife (ti won m pe ni Yunifasity Ife) nigba naa, nibi ti o ti keko gboye lori imo ede Oyinbo (English), ni odun1973, pelu Masita ninu ede kan naa ni odun 1977. O tun kawe gboye MBA ni yunifasiti Eko.
O ti se ise olukoni ri ni ile eko giga okunrin ni Eko (Eko Boys High School), ati eka imo ede oyinbo, ti yunifasiti OAU. O tun sise ni Banki Apapo Ile NAijiria (CBN), awon Ile Ifowopamo Chase Merchant Continental Merchant, ki o to lo da duro fun ra re ti o n se ise igbanimoran fun awon ile ise owo.