Friday, July 3, 2009

ADAJO PASE KI OGA OLOPAA MA MU AGBEJORO AREGBESOLA.

Ile Ejo giga kan ni Ipinle Eko ti pase pe ki oga agba olopaa ma se fi owo ofin mu Agba Agbejoro ile Naijiria, Ogbeni Kola Awodein.
Ile ejo naa tun pase fun awon olopaa pe ki won si da atimu agba agbejoro naa duro, titi ti ile ejo yoo fi yiri oro ti o wa nile naa wo.
Awodein je okan ninu awon agba agbejoro ti o n gbejo ro fun oludije fun ipo gomina Ipinle Osun, labe asia egbe onigbale(Action Congress), Ogbeni Rauf Aregbesola, ohun ni o be ile ejo lati gba ohun lowo awon olopaa nipa dida abo bo eto ijomoeniyan ohun.
Won ni awon olopaa ti n gbero ati mu Awodein ti mole, fun pe o safihan akosile awon olopaa lati gbeja Aregbesola, eyi ti awon olopaa ni ayederu ni.
Sugbon agba agbejoro naa ni ki agbejoro ohun Ogbeni Babatunde Fagbohunlu (Agba Agbejoro), fi iwe esun sile lodo Adajo Afeez Dabiri labe iwe ofin ile waodun 1999.
O pe oga agba olopaa ati ijoba Ipinle Osun gege bi olujejo si esun re. Fagbohunlu ro ile ejo lati gba ipe eni ti o ran ohun nise wole.
Nigba ti o gbo oro enu Fagbohunlu tan, Adajo Dabiri pase pe ki oga olopaa ati awon osise re dekun lati mu, tiimole, fiyaje tabi hale mo atimu Awodein.
O ni gbigba laaye ti ohun gba olufisun naa laaye kari gbogbo esun ti o wa nile, titi ti ohun yoo fi yiri oro ejo ti o wa nile wo tan.
Ile ejo naa tun gba Awodein laye lati fun awon olujejo ni Abuja ati Osun ni abajade esun naa.
Won ti sun igbejo di ojo 14, osu agemo ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment