Friday, August 7, 2009

BOKO HARAM: ENI ESU NI WON O -- SULTAN

Sultan ile Sokoto ti so pe awon olori esin musulumi ti setan lati koju ati lati segun iwa esu ti o n lo lowo ni Bauchi, Borno, Kano ati Ipinle Yobe.
Abubakar, ninu oro ti o so pelu ikapa re gege bi Aare Jama'atul Nasril Islam ati Nigerian Supreme Council of Islamic Affairs, so pe ni iwon igba ti esin Islam ko faaye gba darudapo, oun ko ni fi aaye gba egbe apaayan kan tabi egbe alagbapa.
O ni awon musulumi ati esin Islam ko lowo si idoju ko awon agbofinro, ati fifi eje alaise sofo ti o n lo lowo ni awon ipinle mererin ti Boko Haram ti n da ilu ru.
Sultan naa tun ni ona buburu kan re lati ba oruko rere orile ede yii je niwaju ajo agbaye ti a ko si ni gba.
O wa ro gbogbo Musulumi lati ran ijoba lowo pelu awon agbofinro lowo lati kese jari nibi sise iwadi lori oro idaluru Boko Haram ati awon olori re.

WA OJUTU SI ORO AABO, ONOVO.

Ajo awon gomina ile Naijiria ki oga olopaa tuntun Ogbeni Ogbonaya Onovo ku oriire ti ipo tuntun pelu imoran pe ki o ba wa dekun iwa janduku ati ai ni ibale okan.
Ki Aare Yar'adua to so di oga olopaa tuntun ni Ojoru ti o koja, o ti n soju fun Ogbeni Mike Okiro ti o jowo aaaye re ni ojo24, osu keje odun yii.
Awon gomina ro pe won ti royin re gege bi akoni ti o mo ise re se, ti o si ma n yege ninu gbogbo ise ti won ba fun se, won wa ni ki o tete bere ise ki o si se atunse si ise olopaa ati ki o si se eto aabo ti o peye fun awon ara ilu, awon paa paa ko ni sin lati ran an lowo nibi ti o ba to ati ibi ti o ye lati le kese jari ise re.

OWO MEKA GBOWO LORI

Ajo ti o n moju to irinajo meka iyen NAHCON, salye ni ano pe idi ti owo meka odun yii yoo fi gbowo leri ni pasiparo owo naira si dola.
Komisonati o n gbenuso fun NAHCON, Dokita Saleh Okenwa so fun awon oniroyin lanaa pe ida 12% ti o gori owo naa ko sai da lori pasiparo owo naira si dola, pelu awon idi miran.
O ni awon ti o n lo si ile Meka san owo N470,736 si N588,709, o da lori ibi ti onikaluku ti fe gbe ra ati iru awon ti o m ba lo. O ni pasiparo dola ti o je $1 si N117 lodun to koja ti di $1 si N147 ni odun yii.

AWON AJINIGBE JI ALAGA KANSU MEJI GBE O

Alaga Ijoba Ibile Igalamela/Odolu, Hon. Ernest Abah ati Alaga Iwoorun Yagba(West), Hon. Ropo Asala ni a gbo pe won ji gbe ni ano ni ile itura kan ni Kabba.
Awon mejeeji lo si igboro lati lo kopa nibi ipade awon alaga ijoba ibile ti won ma n se ni osoosu ni ipinle naa ni.
Awon ajinigbe naa pa meta ninu awon olopaa ti o n tele won, nigba ti awon olopaa pa eyo kan ninu awon ajinigbe naa.
Awon ajinigbe naa ti de si ile itura naa ni nkan bii aago meje owuro ninu oko Toyota Hilux ti awon olopaa meji ti won si ko nnkan ija oloro dani tepon.
Asoju alaga ibile Okene, Hon. Yahaya Karaku ti won m pe ni Yakubu ati direba re ti won sese gan an ni won ti ko lo si ile iwosan nla kan ni Lokoja fun iwosan.
A tun gbo pe awon ajinigbe naa tun kede pe ki awon alaga to ku bo sita laijebe, eyi ti won ba ka mo inu ile yoo da ara re lebi, eyi ni o mu ki gbogbo won bere sii ni jade ti won fi ni ki won ma dobale sile ki won ma doju bole.
A gbo pe ni asale ano, awon ajinigbe naa pe komisona fun eto ijoba ibile ati oro loyeloye, Ogbeni Toluwaju Faniyi pelu foonu Abbah pe awon yoo gba milionu 60 owo naira lati fi won sile.

ETO ISUNA 2010, GBOGBO YIN LE O DASI.

Ile Igbimo Asofin Agba, iyen sineti ti so pe eto isuna odun 2010, gbogbo ara ilu lo laaanfani ati dasi.
Alaga Ajo Sineti lori oro isuna, iyen Sineto Iyiola Omisore ni o so eyi di mimo pe gbogbo eeyan ti oro ba kan ni yoo lanfani ati dasi oro eto isuna odun 2010 nitori awon yoo te pepe re sile fun gbogbo awon ti oro ba kan ni lati so ero ti won.
O so eyi di mimo nigba ti o n soro nibi apeje kan ni ilu Abuja ni ana lori oro bi eto isuna owo yoo se ma je nnkan ti o han si awon ara ilu, o ni lati le mu ki eyi je sise, awon yoo kan si awon ti oro ba kan kaakiri origun mefefa orile ede yii.

Monday, July 13, 2009

ERO AMUNA WA PA EEYAN META LEKOO.

Ariwo ekun ni o so ni agbegbe Ibiye, ni Morogbo, agbegbe Agbadarigi ni Ipinle Eko, ni opin ose nigba ti iroyin iku oko ati iyawo kan ati iya iyawo te won lowo latari eefin ero amuna wa naa ti o pa won.
Awon omo won meji wa ni ile iwosan ti a ko mo, sugbon won ti gbe oku awon oku meteeta lo si aaye igboku si ile iwosan apapo ti Badagiri.
Ekunrere alaye oun ti o pa won si sokunkun, sugbon awon olopaa ni oku awon eeyan naa pelu awon omo won obinrin meji ti won da ku ni awon olopaa pelu iranlowo awon ara adugbo gbe jade ni ano lati inu ile won.
Awon olopaa ni won wa bi igba ti eeyan sun ni nigba ti awon wole lati lo ran won lowo ninu iyara kan soso ti won n gbe nigba ti awon de be.
Alukoro awon olopaa ni Ipinle Eko , Ogbeni Frank Mba salaye pe awon olopaa n wa di isele naa lowo.

GOMINA DANIEL ATI AWON OSERE RANTI OGUNDE LEYIN ODUN 19

Gomina Ipinle Ogun, Gbenga Daniel pelu awon egbe osere darapo mo awon ebi, ni opin ose, ti o koja lati se iranti oloogbe Hubert Ogunde, eni ti o ku ni odun 19 seyin.
Ni ibi ayeye naa ti won ti si ere oloogbe naa, Gomina Daniel sapejuwe oloogbe naa gege bi eni itan, ti oruko re ko pare bi odun se n gori odun, ti osu n gori osu.
Daniel se ileri pe ijoba ohun yoo ni ifowosowopo pelu awon ebi Ogunde lati da abule fiimu ti o ba ti agbaye mu sile loruko Ogunde ni Ososa, ilu oloogbe naa.

Friday, July 3, 2009

AYANGALU DAGBERE FAYE NI OMO ODUN 65.

Onilu pataki kan ti gbogbo eeyan mo si Ayangalu, iyen Ayantunji Amoo ti ta teru nipa o.
Gege bi atejade ti Ogbeni Tunde Kilani, onse fiimu pataki te jade fun awon oniroyin, Ayangalu ku ni Ojobo ano, won si sin ni ojo kan naa gege bi ilana musulumi.
Kelani ni a gbo iro iku ayan naa pelu ibanuje ni owuro yii. Iku re tun ti din okan ku ninu awon agbaoje idi ilu ti o tun ku ni ile yooba.
Won ni o ba won se ninu ere Oba Koso, Awon Omemu, Saworoide ati Agogoeewo ati awon ere miran lorisirisi.

GBENGA DANIEL GBENA WOJU AGBENUSO ILE IGBIMO ASOFIN AGBA.

Wahala kan ti o jo ere idaraya sele ni ojobo ano, ni agbegbe Sango, ni Ipinle Ogun, nigba ti gomina Gbega Daniel koju oludamoran Agbenuso Ile Igbimo Asofin Agba lori igbohun soke sodo, Oloye Kayode Odunaro ni gbangba.
Awon ti o te le gomina ati awon ero iworan ri bi Daniel se koju oludamoran naa pe ki lo n se ni ori afara ti won n se lowo.
Gomina ti o se abewo lo si ijoba Ibile AdoOdo/Ota duro nigba ti o ri awon eeyan ti won n dari awon osise ile ise ero amohunmaworan ti won ya ise ti won n se pelu Odunaro lori afara naa.
Daniel ti awon osise ijoba tele leyin wa duro, o bi Odunaro pe ki ni eyin eeyan yii n se nibi, a bi eyin ni e tun moju to ise yii ni.
Oludamoran naa ko tete soro, o kan rerin pe "olola julo, a kan n wo ise ti won n se ni, won ti bere lati ojoAje".
Daniel wa kuro niwaju re nigba ti o fesi re tan.
Ipinle naa ati Agbenuso Agba Saburi Dimeji Bankole ti n se bi ologbo ati ekute lati igba ti agbenuso naa ti kede pe ijoba apapo ti san owo bilionu 1.5 bi ose meloo kan seyin pe ki won fi pari ise naa.

ADAJO PASE KI OGA OLOPAA MA MU AGBEJORO AREGBESOLA.

Ile Ejo giga kan ni Ipinle Eko ti pase pe ki oga agba olopaa ma se fi owo ofin mu Agba Agbejoro ile Naijiria, Ogbeni Kola Awodein.
Ile ejo naa tun pase fun awon olopaa pe ki won si da atimu agba agbejoro naa duro, titi ti ile ejo yoo fi yiri oro ti o wa nile naa wo.
Awodein je okan ninu awon agba agbejoro ti o n gbejo ro fun oludije fun ipo gomina Ipinle Osun, labe asia egbe onigbale(Action Congress), Ogbeni Rauf Aregbesola, ohun ni o be ile ejo lati gba ohun lowo awon olopaa nipa dida abo bo eto ijomoeniyan ohun.
Won ni awon olopaa ti n gbero ati mu Awodein ti mole, fun pe o safihan akosile awon olopaa lati gbeja Aregbesola, eyi ti awon olopaa ni ayederu ni.
Sugbon agba agbejoro naa ni ki agbejoro ohun Ogbeni Babatunde Fagbohunlu (Agba Agbejoro), fi iwe esun sile lodo Adajo Afeez Dabiri labe iwe ofin ile waodun 1999.
O pe oga agba olopaa ati ijoba Ipinle Osun gege bi olujejo si esun re. Fagbohunlu ro ile ejo lati gba ipe eni ti o ran ohun nise wole.
Nigba ti o gbo oro enu Fagbohunlu tan, Adajo Dabiri pase pe ki oga olopaa ati awon osise re dekun lati mu, tiimole, fiyaje tabi hale mo atimu Awodein.
O ni gbigba laaye ti ohun gba olufisun naa laaye kari gbogbo esun ti o wa nile, titi ti ohun yoo fi yiri oro ejo ti o wa nile wo tan.
Ile ejo naa tun gba Awodein laye lati fun awon olujejo ni Abuja ati Osun ni abajade esun naa.
Won ti sun igbejo di ojo 14, osu agemo ti a wa yii.

Tuesday, June 30, 2009

OKIRO PASE KI AWON INILE ITURA MA MORUKO AWON ALEJO WON WA LOJOOJUMO

Oga Agba olopaa yanyan, Ogbeni Mike Okiro, ti pase fun awon onile itura ni orile ede yii, pe ki won ma mu idanimo awon ayale gbe won wa si odo awon olopaa ni ojojumo.
O ni eyi se pataki nitori yoo je ki awon olopaa le mo onka iye awon eeyan ti o n wole ati jade kuro ni orile ede yii lojoojumo.
Okiro tun ni ti a ko ba moju to awon eto igbafe wa, won le lo ona igbafe lati fi ko ba aabo orile ede wa.
Oga Agba Olopaa naa so eyi di mimo, nigba ti o n gba alejo Oga Agba Eto Igbafe, (NTDC), Ogbeni Segun Runsewe, ni ofiisi re.
O tun ni, lati isinyii lo, awon olusowo ile itura ati aye igbafe miran gbodo ma wo igbese awon ti won ba lalejo, ki won si ma ta olopaa lolobo, ti won ba kofiri ajeji igbese kan.

MO N FI IGBO SE OOGUN NI -- OLUJEJO

Oro kan se bi awada lanaa ni Ile Ejo Giga Ijoba Apapo ni Eko nigba ti olujejo omo odun 48 kan, Wahab Ahmed, so fun ile ejo pe ohun ko ta igbo, sugbon ohun fi n se egbogi arunmoleegun ati awon egbogi miran ni.
Ajo ti o n gbogun ti egbogi oloro ni ile wa, iyen NDLEA, mu olujejo naa lo si ile ejo pelu esun eyo kan pe o n ta igbo niwaju Adajo Binta Murtala-Nyako pe won ka mo pelu igbo ti o won kilo 1.5 lai ni ase ati se bee.
Won ni o se ese naa ni ojo 24, osu keta odun yii, ni agbegbe Dada Bello, ni Ayilate, Agege, Ilu Eko.
Gege bi ajo NDLEA ti wi, ese re naa lodi si ofin abala 11(c) ti ajo NDLEA, Ori N30, ofin Ile wa Naijiria, 2004.
Eni ti won fi esun kan naa ti o ni ohun pari iwe mewa ni odun 1981, gba pe ohun jebi esun naa.
O so siwaju si i pe ohun ma n mu igbo, sugbon ohun ko ti ta igbo ri laye ohun. O ni"o ma n fun mi lokun ati agbara lati le se ise daradara.
"Mo tun ma n fi eyi to gbo sile re se oogun arunmoleegun, ati ogun ti ko ni je ki awon omode mu igbo mo."
Agbejoro ajo NDLEA wa ro adajo lati dajo fun Ahmed bi o ti to ati bi o ti ye.
Adajo Murtala-Nyako da ejo fun Ahmed pe ki o lo si ewon osu merin, ki ounka re bere lati ojo ti won ti mu.

Monday, June 29, 2009

AWON OLOPAA N PA EEYAN SERE NI

Ni igbakeji laipe si ara won, ofin ti ijoba Eko se pe ki won ma mo iku to pa eeyan ki won to sin tun ti se afihan bi awon olopaa se n si ibon won lo pa eeyan sere.
Ayewo ti won se si iku to pa oloogbe Modebayo Awosika labe ofin Coroner naa ti odun 2007, so pe awon olopaa lo se iku pa arakunrin naa lona aito.
Ile Ejo Majisireti ti o wa ni Tapa ni Eko ti Magisireti Agba Phillip Ojo se adari re so pe ni igba ti awon ye esi korona naa wo, o han gbangba pe ibon awon olopaa lo se iku ojiji pa oloogbe naa.

AGBATAN NI KI E GBA WA O, OGAGUN IJAW

Ogbeni Solomon Ngbara, okan ninu awon olori ajagunta Ijaw ti o wa lati apa Ogoni ni Ipinle Rivers ti ke gbajare si ijoba apapo pe agbatan ni ki o gba awon ti o ba ti se tan lati jowo ara won.
Eyi n wa ye lasiko ti Aare Yar'adua n gboriyin fun awon ajagunta naa ti won ti se tan fun ati ko ibon sile di omo tuntun pe ki alaafia le joba ni agbegbe naa ati orile ede Naijiria lapapo.

Tuesday, June 16, 2009

AWON OLOPAA MU IGBAKEJI AGBENUSO IPINLE EKITI.

Leyin bii osu meji ti awon olopaa ti kede pe awon n wa igbakeji Agbenuso Ile Igbimo Asofin, owo awon olopaa Ipinle Ekiti ti ba Ogbeni Saliu Adeoti ni ano, ti won si fi si ahamo, lori esun pe o lowo si jijo olu ile ise ajo eleto idibo, ni agbegbe Ido-Osi ni lori oro atundi eto ijoba ipinle naa ti o koja.
Won ni won mu ni ile re ti o wa ni agbegbe Otun-Ekiti ni nnkan bi aago kan ano.

AWON AJAGUN IJAW GBA LATI KI OWO OMO WON BO ASO.

Olori awon Ajagun ijaw, iyen Tom Ateke ti o koju awon ologun lowolowo, ti gba pe awon yoo ji owo omo awon bo aso, sugbon o m beere fun iru aforiji ti ijoba apapo yoo fun awon jagunjagun awon, ki awon le mo bi awon se ma se eto ipalemo ati ko ohun ija sile kia kia.
Gbigba lati gba aabo aforiji ijoba ti Ateke gba waye leyin ti awon egbe ajagun miran tun n leri pe awon yoo di ere boolu ife agbaye to m bo lowo.
Agbejoro fun awon jagun jagun ijaw naa, Ogbeni Ikenna Enekweizu, so pe eni ti o gbese fun ohun naa, ti o ti koju orisirisi ija pelu awon ologun ijoba ti se tan lati joo ija nigba ti o pe apejo awon oniroyin ilu Pota ni ano.
Agbejoro naa ni eni ti o be ohun ni se, ti se tan lati pada si Okirika lati lo darapo mo ilosiwaju to n lo ni be.

Monday, June 15, 2009

INA JO OPA EPO ROBI.

Isele ijamba ina tun sele nilu Eko ni ojo Abameta 13, ti o koja ni Ilado, ni itosi aaye itoju epo si Atlas Cove ti ile ise epo robi NNPC.
Eyi sele leyin iru re kan ti o sele ninu osu Igbe (April), ti o koja, ni agbegbe Mosimi ni Ipinle Ogun.
Agbenuso ile ise opa epo PPMC Ogbeni Ralph Ugwu, so pe isele buburu naa n wa waye latari awon ti o nji epo robi wa ni.
O ni awon egbe naa n sise pelu oko mokanla, ti won fi n ji epo wa. Bi won se ri awon eso ogun oju omi ti o m bo ti won fe salo ni isele naa sele.
Awon oniroyin wa hu gbo pe ina jo awon oko won sugbon won ri ona abayo lati sa asala fun emi won.

AWON GOMINA JAWE GBELE E.

A ti hu gbo pe o da bi eni pe ajo awon gomina ile wa Naijiria ti jawe gbele e awon o lo si ile ile unifasiti Havard, ni Boston, Ile America mo.
E ni ti o salaye oro naa so wi pe ariwo ti awon eeyan pa le awon gomina naa ni o fa ti won fi jo o lilo si ile iwe ti won fe lo fun igbeko naa.
Eyi ni o tele pipada bo awon merin kan ti won ti koko lo se iwadi lori oro Havard ati awon ile eko miran ni ilu ohun ni nnkan bii ose meji seyin.
Iwe Iroyin ile Naijiria kan ti ko pe asoju ile eko naa ti so pe ko si akosile ko kan laaarin oun ati awon gomina ile Naijiria pe awon m bo fun igbeko nilu awon.
Eyi ni a gbo pe o doju tii won julo ti won fi wa jawe gbele e fun ra a won.
A gbo pe gbogbo awon gomina ile Naijiria ni won pete pero pe ki gbogbo awon Gomina 36 lo kuro ni ilu yii fun igbeko ni Ilu oyinbo, eyi ti o ti fe fi ori sopon bayii.

Sunday, June 14, 2009

AWON OMO NAIJIRIA SE AYEYE JUNE 12.

Ogun logo awon omo Naijiria lo se ayeye isami odun 16, ayajo ojo June 12, 1993, ti a se idibo Ijoba Apapo ti won ni o kese jari julo ni ile Naijiria, ti won so pe Oloye Mosudi Olawale Kasimawo Abiola jawe olubori julo, sugbon ti ko raye de ipo naa.
Orisirisi imoran ni o jeyo fun ijoba lori ona ati se iranti ojo naa ni ile wa Naijiria, ti oloogbe gbe naa ti o ku si ahamo ijoba ni ojo7,osu 7 odun 1998, latari pe o n beeere fun eto re .
Gomina meji ni ile wa Naijiria, iyen Eko ati Ogun ni won ya ojo naa soto fun awon osise won lati sami ayajo ojo naa.
Gomina Babatunde Raji Fashola so wi pe oku ibo naa yoo si ma le awon omo Naijiria ki ri ayafi ti ijoba ba le se eto lati san ojo fun esi idibo naa ti o yarati julo ni orile ede wa Naijiria.

EGBE OKUNKUN WA NIDI EPO ROBI.

Adari ajo to n moju to oro epo robi (NNPC), tele ri, iyen Dokita Jackson Gaius-Obaseki, ni ojo Bo ti o koja ti so fun Ajo Alabe Sekele Ile Igbimo Asofin Agba ti o n yiri aise deede idi ajo naa wo pe ohun ba ajo naa rudurudu, ni odun 1999, awon ile ise epo kan wa ti won ni iwe ase ati ma a gbon epo robi di odun 2016.
Ko tako tabi gba wole pe ajo naa ni ogbon alumo koroyi ti o n se pelu awon ile ise elepo, sugbon Obaseki so wi pe idi ni yi ti ohun fi doju ija ko awon egbe imule idi epo naa ni odun 1999 ti ohun gba ijoba.
O ni ohun ni lati gba awon iwe ase naa nigba ti ohun ri pe awon ajo elepo naa ko gba ona ti o mo lati ma se ise won.

E RAN WA LOWO O, AMODU, KANU.

Awon abenu gan meji ti o le gbe Naijiria de ibi idije ife eye, Ife Agbaye l'odun to m bo ni ilu South Africa, iyen Akoni mo o gba Shuaibu Amodu ati Agbaboolu, Nwankwo Kanu ti pe fun ifowosowopo gbogbo omo Naijiria, ki aba naa o le di mimu se.
Won soro nibi apeje ti ile TomTom se pelu awon oniroyin pe ayafi ki awon omo Naijiria duro ti awon digbin, bi awon se n mura sile lati koju awon Carthage Eagle ni Satide to m bo yi ni papa isere November 7, ni ilu Rades.

NDLEA SAWARI IBUDO AWON ELEGBOGI OLORO NI PAPA OKO OFURUFU.

Oga agba ajo ti o n gbogun ti egbogi oloro nile wa Naijiria, iyen(NDLEA), Ahmadu Giade ti se ileri, lati da seria to peye fun gbogbo awon ti o ba lowo ninu ipago ibi ti awon onise ibi ti o n gbe egbogi oloro gba ona ti awon agbofinro ko ti ni ri won wo inu oko ofurufu ni papa oko ofurufu Ilu Eko, lati dekun iwa buburu naa patapata.
Giade so eyi di mimo lanaa ni papa oko ofurufu naa nigba ti o n soro pelu awon oniroyin latari meji miran ti won tun mu ninu awon ti o n gba ona eburu gbe apamo awon onise ibi gbona eburu wo inu oko ofurufu ti owo awon agbofin ro kii fi i to won.
O ni ajo awon ko ni sin mi titi ti awon yoo fi mu gbogbo awon eeyan ti o mo nipa bi won se n se ise yii ti awon si fi won jofin, o wa ro gbogbo awon omo Naijiria lati ma se akiyesi daradara ati lati ran an ajo awon lowo lati le kese jari ninu ija ati dekun gbogbo ohun to n je egbogi oloro ni orile ede yii.

E FI EJE TORO OSOTIMEHIN RO AWON OMO NAIJIRIA

Lati dekun ri ra eje ti o ti labawon lowo awon ti o n ta eje orisirisi kiri nitori owo, Minisita fun eto Ilera, Kofeso Babatunde Osotimehin ti ro awon omo Naijiria lati ma a fi eje toro ni ofe fun anfa ni atile ni anito fun eto ilera to peye.
Minisita ti o pe ipeyi nilu Abuja lasiko ti o n ba awon oniroyin soro, nibi ayeye ayajo Ojo Awon Afeje Toro L'agbaye, so pe ona kan lati le je ki anito, aabo, ati pipo ba oro eje, ni lati ri eje gba lodo awon ti o n fi eje toro la i gba owo lori re.

Friday, June 5, 2009

AJO ONIROYIN EKO SO LADI LAWAL LORUKO.

Ajo awon oniroyin ile Naijiria, eka ti Eko (NUJ), ni ola ode yii, yoo yi oruko olu ile egbe won ati sekiteria won pada si oruko alaga won ti o ku, Alhaji Ladi Lawal.
Yiyi oruko olu ile egbe naa pada si Ladi Lawal Press Centre je okan lara ona ti egbe naa fe fi ranti Aaare egbe naa, gomina Adams Oshiomhole ti ipinle Edo ni yoo si dari re.
Ayeye ranpe naa ti o ma waye ni bii aago 9 owuro si aago11 ni ojule 9a Adugbo Iyalla, Alausa, Ikeja ni be awon eeyan yoo raye lati gboriyin fun akoni naa ti o lo.
Ladi Lawal, omo odun 54, ti o ku ni Abuja bi ose meji seyin, se Alaga fun egbe naa l'Ekoo ni eemeji ati Aare egbe naa fun Naijiria ni odun 1994 si 1995.

KADUNA FI ENI YE LUKA SI.

Ijoba ipinle Kaduna ti ya eni so to gege bi ojo ko si ise fun awon ara ilu lati ye oloogbe ogagun Agba Luka Yusuf, ti o ku ni ojo 2, osu yii.
Atejade ti asoju ijoba fun (eto iroyin eto gbagba), iyen Umar Sani fowo si salaye pe pelu isinmi eni, gbogbo ise ijoba ni o ti yi pada, paapa julo eto abewo kaaakiri gbogbo ijoba ibile ti o n se lowo ni awon yoo tu sun si ojo iwaju.
"Gomina ki gbogbo awon ebi oloogbe naa, Ile ise ologun ile wa, pelu gbogbo omo ipinle yii pe a ku araferaku omo wa ti o lo, yoo si ro wa loju fun ogidi omo ti o sise takuntakun sin ilu re".

ELEWO TUNTUN YOO GBA OPA ASE LOLA.

Elewo ti ilewo tuntun ni Abeokuta, ipinle Ogun, Oba Akindele Orisabiyi, Elewo dodo bi oke 11, yoo gba opa ase lola.
Oba Elewo ti o ti wa ni ipebi lati igba ti gomina ti gba yiyan re wole, ni Gomina Gbenga Daniel yoo gbe opa ase fun lola gege bi Oba.
Oba ti won bi ni bi odun 67 seyin je akeko jade Yunifasiti Obafemi Awolowo, Ile Ife (ti won m pe ni Yunifasity Ife) nigba naa, nibi ti o ti keko gboye lori imo ede Oyinbo (English), ni odun1973, pelu Masita ninu ede kan naa ni odun 1977. O tun kawe gboye MBA ni yunifasiti Eko.
O ti se ise olukoni ri ni ile eko giga okunrin ni Eko (Eko Boys High School), ati eka imo ede oyinbo, ti yunifasiti OAU. O tun sise ni Banki Apapo Ile NAijiria (CBN), awon Ile Ifowopamo Chase Merchant Continental Merchant, ki o to lo da duro fun ra re ti o n se ise igbanimoran fun awon ile ise owo.

FALANA TA AWON ASOFIN JI.

Alaga Awon Agbejoro Ile Afirika, ti o tun te agbjoro pataki kan ni Eko, Ogbeni Femi Falana ti so wipe ki awon omo ile igbimo asofin Eko ji giri si ise ofin ni sise lati le soju awon ti o yan won daradara.
O so eyi di mimo nigba ti o n ba awon asofin naa soro lati sami odun meji ti won ti yan won gege bi alase eleekefa si aye naa ni Alausa, o ni won ti gbiyanju pelu awon aseyanri gomina Babatunde Raji Fashola, (SAN), sugbon ki won tun bo jara mo ise sii ki ere iselu le te omo ti won ko tii bi lowo.

AWON JAGUNJAGUN IJOBA NI AWON KO JI EPO O.

Awon eso ologun ti o ti n kooola pelu awon ologun ijaw ni agbegbe Niger Delta ti so pe iro patapata ni esun pe awon n ji epo robi ile wa ta ti awon egbe ti o n ja fun eto awon ijaw fi kan awon.
Eyi n wa ni asiko ti oga awon Ajo kan ti o n ri si atunse Awon Agbegbe Niger Delta, Ogbeni Emmanuel Aguariavwodo n pe fun awon omo won pe ki won ko ako sile, ki won wa alafia fun ara won.
E ni ti o tako esun awon omo Ijaw naa ni asoju fun oro iroyin fun awon jagun jagun ijoba, Ogagun Rabe Abubakar, ti o so pe opolopo nnkan nnkan rere ni awon jagunjagun ijoba ti se ni dara fun orileede won ati awon ara agbegbe Ijaw ju ki awon kan wa fenu tan ise won lo.

GOMINA DANIEL PASE PE KI WON FO IJEBU ODE MO.

Ajo kan ti gomina ipinle Ogun da sile, ti bere ise pereu lori oro imototo ni ipinle naa ati agbegbe re, ati ipenija fun awon ara ipinle Ogun ati Ijebu Ode ati awon agbegbe re, lori bi won yoo se, wa ni imototo titi ti won yoo fi se eto ati leyin idije Ife Agbaye ti U-17, ti ipinle naa fe gba lalejo.
Eto naa fe waye ni ipinle naa latari ajo FIFA, gomina ipinle Ogun, Gbenga Daniel ati Ajo ti o n se eto abele ajo naa.
Alaga ti Ijebu-Ode fun ajo naa, Ogbeni George Taylor so pe pelu bi gomina se bo si ta lati kede eto imototo naa, o fi han gbangba, iru iha ti o ko gbigba alejo ere boolu naa.

UGBANE, ELUMELU BO, WON TUN HA.

Ija yii ko ti kan fun alaga, Ajo Ile Igbimo Asofin Agba (Sineti), fun Agbara, Iyen Nicholas Ugbane, ati elegbere ni Ile Igbimo Asofin Kekere Iyen, Ndudi Elumelu; oga agba yanyan ni ile ise oba eka Amusagbara, Dokita Abdullahi Aliyu ati awon toku ti won jo nje ejo lori owo ina igberiko ti won ko je.
Bi won se tu won sile ni ogba ewon Kuje, ni Abuja, pe ki won ma lo si ile, enu ona ogba ewon naa ni owo sikun ajo EFCC tun ti te won pe won ni awon ibeere dahun si lodo ti awon naa.

Wednesday, June 3, 2009

ILE IGBIMO ASOFIN PASE PE KI ALAGA KANSU DA OWO OSU PADA.

Ile Igbimo Asofin Ipinle Ogun ti ro alaga fidi e Erekusu Ijebu (Ijebu-North), Omoba Wale Osiyemi lanaa pe ki o da owo ti o na, owo osu ti o gba ati gbogbo eto ti o je gege bi alaga fidi e pada lati igba ti o ti gba ijoba lowo alaga ti won dibo yan.
Ile Igbimo naa ti tu isejoba fidie naa ka lati ose ti o koja, lori esun pe Gomina Gbenga Daniel kan se ni arumoje ni lona ti ko bofin mu.
Alaga ti won di ibo yan ni agbegbe naa, Ogbeni Tele Ogunjobi, ni Daniel jawe jokoo le fun ni nnkan bi osu marun seyin, latari pe ohun ni o wa leyin wahala ti o sele ni Olu Ile Egbe PDP ni Abeokuta lodun to koja, ti o si mu emi eeyan meta lo.
Osu marun leyin igba ti o ti yo, Daniel ko ti da pada, eyi ti o mu ki Ile Igbimo Asofin so pe iwa ti Daniel wu yi ko bojumu, ko si ba ofin mu.
Abati ano waye ni gbagede Ile Igbimo naa latenu Asofin Adijat Adeleye-Oladapo ti o n soju Ifo 2, nigba ti Asofin Abiodun Micheal Akovoyo ti o n soju Ipokia, se gbe lese.

KOMISONA OLOPAA PE OGA RE ATI IJOBA LEJO.

Komisona olopaa ti o si wa lenu ise iyen Ogbeni Abayomi Dolapo Onashile ti o n sise ni ni Abuja, ti pe oga agba yanyan olopaa ati ijoba apapo lejo pe won gbodo fun ohun ni ipo ipele keta oga agba yanyan ti o ti to si ohun ki won to ni ki ohun lo fi eyin ti lenu ise.
Onashile, ti o n sise ni Louis Edet House, olu ile ise olopaa ni Abuja n gbadura si ile ejo lati bawun dekun ijoba apapo tabi awon osise re lati seto ifeyinti fun ohun titi ti won yoo fi fun ohun ni ipo ti o to si ohun.
Ninu ipejo ti Farouk Asekome mu lo si ile ejo, o pe Agbejoro Orilede Patapata (AGF) ati Ajo to n ri si ise olopaa (PSC), ni olujejo, o wa ni yato si pe ki won fun ohun leto ohun bi o ti ye, ki won kuku ni suuru fun ohun lati lo odun merin miran si ninu ise olopaa fun pe won da agbega ohun duro.
Ninu iwe esun ti o koko waye, olufejosun fi esun kan ijoba pe won da ohun duro ni odun 1998 lenu ise lai nidi, nigba ti ile ejo si da ohun pada ni osu Agemo odun 2000 ti ile ejo giga se.
Ninu idajo naa ti ijoba ko tako, ile ejo ni so pe ki won gba ohun pada senu ise, igbega lenu ise ati owo osu ohun de gudo maa lo deede nigba ti o ba ye bi won se n se fun awon ti o ku lenu ise.

OWO SIKUN TE AGBERO MARUN NIPINLE OYO

Owo sikun awon olopaa ti te marun ninu ajo awon adari oloko ero latari darudapo ti o wa ye laaarin won fun didu olori, ti o si mu itaje sile dani.
Darudapo naa waye latari ija abele ti o waye laaarin alaga, Alhaji Lateef Akinsola, ti gbogbo eeyan mo si Tokyo, ati igbakeji re ti o n je Alhaji Lateef, ti gbogbo eeyan si tun mo si Elewe-omo.
Darudapo yii mu ki awon oloja ati aladugbo ni agbegbe Gate Agodi sa asala fun emi won, o si di ija ti o mu itajesile wa.
O keere tan, eeyan mewa fara pa, ti o si ko ijaya ati siba sigbo ba awon ara ilu fun wakati ti o po, nigba ti ija naa fi n lo.
Awon olopaa ti mu marun ninu awon to n ja naa, nigba ti awon olopaa tun ni awon si tun ti ko olopaa pupo si agbegbe naa.
Enikan kan ti o mo idi ija naa ni o waye latari pe Elewe-omo fe ye aga nidi Tokyo ki o to di odun 2011 ti yoo gbe ijoba sile.

ADAJO SUN IGBEJO IBO OSUN SI OJO 12, OKUDU

Igbejo lori makaru u ti o wa ye ninu eto idibo ti Ipinle Osun ni odun 2007, ni awon adajo ti Adajo Garba Alli je olori fun ti sun siwaju di ojo12, osu kefa (Okudu), ti a wa yii.
Awon adajo naa tun fi idajo lori ejo kan ti olufejosun Enjinia Rauf Aregbesola ati olujejo re Gomina Olagunsoye Oyinlola si ojo 11 osu kan naa.
Awon agbejoro to soju fun olufejosun nii: Oloye Ebun Sofunde, SAN, Oloye Akin Olujimi, SAN, Oloye Rotimi Akeredolu, SAN, Oloye Kola Awodein, SAN, Oloye Charles Edosomwan,SAN, Ogbeni Deji Sasegbon,SAN, ati Kofeso Yemi Osinbajo, SAN.
Awon to soju Gomina Oyinlola ni: Mallam Yusuff Olaolu Alli, SAN, Oloye Tayo Oyetibo, SAN, Otunba Kunle Kalejaye, SAN, Ogbeni Lawal Rabana, SAN, ati Ogbeni Nathaniel Oke, SAN.
Ni igba ti igbejo tun bere ni ano, Alli so fun ile ejo naa pe, ni ojo Aje 1, osu yii, ti fiwe sile lati tako aba Aregbesola Lati tun mu awon eleri miran wole leyin eyi ti o ti wa nile tele.
Aregbesola ti ro ile ejo tele ri pe ki ohun pe awon eleri wa si i lati wa jeri si ayewo awon nnkan idibo ti won yewo lodo awon ajo eleto idibo ni ojo14, osu Igbe ti odun2007 fun ibo gomina ti won se ni Ipinle Osun.

INEC JEWO PE AWON BURA FUN AWON OSISE AWON

Ajo ti o m boju to eto idibo ile wa Naijiria, Iyen INEC ti jewo pe awon se ibura fun awon osise awon, sugbon won ni iru ibura bee ko nii se pelu eto idibo ti o wa ye ko ja ni Ipinle Ekiti.
Eni ti o dele adari ipolongo ajo naa, Ogbeni Emmanuel Umenger, so pe won se eto ibura . O wa ni irufe ibura bee ko ni se pelu atundi ibo ti o koja ni Ipinle Ekiti. O ni "bibura lati pa asiri mo ki i se ajo awon nikan lo n se, sugbon gbogbo ise to ba ti je ise elege bi ti wa yii ni won ma n se ibura fun awon osise won.
"E to ti o ye ki a se ni a se lori awon osise wa, ko ni oun kan, kan se pelu eto atundi ibo Ekiti rara", bi Umenger se so.

Tuesday, June 2, 2009

LADIPO TAKO IKOLU AMODU NILU LONDONU.

Aare egbe awon omo Naijiria ti o n ye awon agbaboolu si, iyen Dokita Rafiu Ladipo ti ta ko kikolu ti awon omo Naijiria kan kolu akoni gba Suaibu Amodu ni ilu Ireland nibi boolu olorejore ni ojo Jimo ti o koja pe ko boju mu.
Dokita Ladipo ti o saaju awon amode dun lo sibi ere boolu naa ni ilu Londonu so wi pe ki se asiko yii ti awon agbaboolu Super Eagles n se daadaa ti won si n sun mo ati gba ase ati kopa ninu idije ti Mundial ni South Africa ti o m bo ni o ye ki enikeni wa ma di won lowo.

ASIRI AWON TO N TI AWON JAGUNJAGUN IJAW LEYIN TU.

O da bi eni pe kikoju ti awon eso ologun lo koju awon jagun jagun ijaw ni ano ojo aje 1/6/2009, ni Oporoza,niGbaramatu Kingdom ti n so eso rere bo, nibe ni won ti ri awon asiri pe awon osise ijoba agba wa lara awon ti o n ran awon jagunjagun naa lowo lati se ise ibi won.
Awon alatileyin won toku ni awon osise epo, ati awon ara ilu okeere.
Eni kan ninu ijoba so fun wa pe awon iwe asiri ti won ri ko ni ibi ikale olori awon jagunjagun ijaw naa, Oloye Government Ekpemupolo (ti gbogbo eeyan mo si Tompolo), fi han pe awon oloselu ati awon olye agbegbe naa mo bi won sen ji epo ati bi o se n di tita ni fun awon ara okeere.

IJOBA O TA NITEL MO O

Ajo ti o n seto tita nnkan ijoba ti gba ase pe won ti ta ile ise igbohunsafefe (NITEL) lowo ile isenla kan ti o n je Transnational Corporation plc.
Ase naa waye gege bi Adari Agba Ajo to n seto tita ohun ini ijoba, Dokita Christopher Anyanwu ti wi pe a i le ri owo ida 51 ti won fun won lati odun 2006 san, ni o fa sababi gbigba ase naa.
Anyanwu ti o tun ba awon oniroyin soro leyin ipade won nilu Abuja, so pe gbogbo ile ise ti won ba ta ti awon ti o ra ko ba ti pe adehun won gege bi ofin ti won jo bu owo lu ni awon yoo yewo bi o ti to ati bi o ti ye.

YAR'ADUA PAARO GOMINA ILE IFOWOPAMO AGBA

Aare Orile ede Naijiria, Alhaji Umaru Musa Yar'Adua ti fi oruko Adari gbogbo gboo ti ile ifowopamo First Bank, iyen Mr. Sanusi Lamido Sanusi sowo si ile Igbimo Asofin agba fun ayewo fun ipo gomina baanki apapo ole Naijiria (CBN).
Ti ile igbimo asofin agba ba faramo, ohun ni yoo gbase lowo gomina ano Kofeso Chukwuma Soludo ti asiko re gege bi adari banki apapo ile Naijiria sese pari.
Iwe Iyanyan ti agbo pe Aare Yar'Adua fi sowo naa ni a gbo pe o te awon alase lowo ni osan ano, won yoo si ka si eti awon asofin toku leni.
Yar'Adua ti gboriyin fun Soludo ninu leta ikini ku oriire re ti awon oniroyin ri gba, o sapeju we Soludo, gege bi akin ti o se ojuse re nigba ti o ye fun ilu re, Naijiria, ti o si han si gbogbo aye pe o se bee. O dupe pupo fun loruko ara re gege bi aare, ati loruko gbogbo omo Naijiria lapapo pe o se e.
Leyin eyi, YAr'Adua ti so pe ohun tun ti tun Ogbeni Tunde lemo yan fun igba ekeji gege bi igbakeji Gomina apapo banki ile wa naa.

Monday, June 1, 2009

O DE O, TUNTUN NI.

Gbogbo akitiyan iwe iroyin okiki lateyinwa, lati gbe iwe iroyin olojoojumo jade ti n ja si pabo ti pe, a i sowo baba ijaya ma ni, sugbon a dupe, fun anfani ero alatagba ayelukara yii, ti o pese anfani to yanranti yii, ise ti wa di sise okunrin to ku si ile ale.
Lojoojumo, ni a o ma ko iroyin to n ja de lorile ede Naijiria wa jade fun kika gbogbo eeyan to feran yoruba ni kika, a o si ri pe gbogbo nnkan ti a ko jade, ooto inu ni a o fi tele, a o ni fi igba kan bo okan ninu rara.
Bi o ba se n sele, ni igbona ihooru bi won se n je opolo ni a o se ma mu wa fun yin.
Gege bi e si ti se mo, ki i dun ko po, a o gbiyanju lati ma ma a gba yin lasiko to po, a o ri pe soki soki bi obe oge ni a n se awon iroyin naa.
Awon ewa ede to dangajia, ti ko si ni nira ju paapaa ni a o gbiyanju lati maa fi gbe ede kale.
Ede yoruba ti o ro run julo, ni a gbegbe ti siso yoruba ti o rorun julo nila adulawo Afirika wa, iyen Ipinle Eko, ni a o ma fi ko iroyin wa, e ku oju lona.